Javascript must be enabled to continue!
Àgbéyẹ̀wò Ìlò-Èdè Nínú Orin Ìbílẹ̀ Ìlọrin
View through CrossRef
Ọ̀kan pàtàkì tí kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn lára ẹ̀ka tí lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá pín sí ni orin jẹ́. Bárakú sì ní ọ̀rọ̀ orin láwùjọ ọmọ ènìyàn pàápàá jù lọ àwọn Yorùbá nítorí pé onírúurú ààyè ni orin ti máa ń jẹ jáde nínú ìgbésí-ayé wọn lójoojúmọ́. Bí àwọn akọrin àwùjọ bá sì ń ṣiṣẹ́ ọnà wọn, ìjìnlẹ̀ èdè tó jinná ni wọ́ n fi máa ń gbé e jáde tí yóò sì máa ṣàfihàn bí irú àwọn akọrin bẹ́ ẹ̀ ṣe gbọ́ èdè àti ìmọ̀ nípa àṣà àwùjọ tó ti ń kọrin nítorí pé ìpohùn ìbílẹ̀ èyí tí orin jẹ́ ọ̀ kan pàtàkì lára wọn dà gẹ́gẹ́ bí àwògbè tàbí díńgí tí a fi ń ríran rí àwùjọ. Ìlò-èdè tó jinná kò sì ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn kí àgbékalẹ̀ orin wọ̀nyẹn lè rídìí jòkó dáadáa kí wọ́n sì lè wu etí í gbọ́. Nínú iṣẹ́ yìí, a ṣe àgbéyẹ̀wò àtí àtúpalẹ̀ díẹ̀ lára àwọn ọnà-èdè tó ṣúyọ nínú àṣàyàn orin ìbílẹ̀ Yorùbá Ìlọrin bíi dàdàkúàdà, bàlúù, wákà, kèǹgbè, sẹnwẹlẹ, kàkàkí/bẹ̀ ǹbẹ́ , Orin ọlọ́ mọ-ọba Ìlọrin,orin agbè àti àwọn mìíràn. Lára àwọn ọnà-èdè tí a gbéyẹ̀ wò ni àwítúnwí, àfiwé, ìjẹyọ ẹ̀ ka-èdè, àyálò-èdè àti ipa ‘Creole’ nínú orin ìbílẹ̀ Ìlọrin. Iṣẹ́ yìí ṣàfihàn pé iṣẹ́ ọpọlọ tó jinná ni orin kíkọ àti pé àwọn ọnà-èdè tó máa ń ṣodo sínú wọn lóríṣiríṣi ní iṣẹ́ tí kálukú wọn ń jẹ́ láti túdìí òkodoro nípa àṣà, ìṣe àti èdè àwùjọ tí onírúurú àwọn orin náà ti ń jáde
Title: Àgbéyẹ̀wò Ìlò-Èdè Nínú Orin Ìbílẹ̀ Ìlọrin
Description:
Ọ̀kan pàtàkì tí kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn lára ẹ̀ka tí lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá pín sí ni orin jẹ́.
Bárakú sì ní ọ̀rọ̀ orin láwùjọ ọmọ ènìyàn pàápàá jù lọ àwọn Yorùbá nítorí pé onírúurú ààyè ni orin ti máa ń jẹ jáde nínú ìgbésí-ayé wọn lójoojúmọ́.
Bí àwọn akọrin àwùjọ bá sì ń ṣiṣẹ́ ọnà wọn, ìjìnlẹ̀ èdè tó jinná ni wọ́ n fi máa ń gbé e jáde tí yóò sì máa ṣàfihàn bí irú àwọn akọrin bẹ́ ẹ̀ ṣe gbọ́ èdè àti ìmọ̀ nípa àṣà àwùjọ tó ti ń kọrin nítorí pé ìpohùn ìbílẹ̀ èyí tí orin jẹ́ ọ̀ kan pàtàkì lára wọn dà gẹ́gẹ́ bí àwògbè tàbí díńgí tí a fi ń ríran rí àwùjọ.
Ìlò-èdè tó jinná kò sì ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn kí àgbékalẹ̀ orin wọ̀nyẹn lè rídìí jòkó dáadáa kí wọ́n sì lè wu etí í gbọ́.
Nínú iṣẹ́ yìí, a ṣe àgbéyẹ̀wò àtí àtúpalẹ̀ díẹ̀ lára àwọn ọnà-èdè tó ṣúyọ nínú àṣàyàn orin ìbílẹ̀ Yorùbá Ìlọrin bíi dàdàkúàdà, bàlúù, wákà, kèǹgbè, sẹnwẹlẹ, kàkàkí/bẹ̀ ǹbẹ́ , Orin ọlọ́ mọ-ọba Ìlọrin,orin agbè àti àwọn mìíràn.
Lára àwọn ọnà-èdè tí a gbéyẹ̀ wò ni àwítúnwí, àfiwé, ìjẹyọ ẹ̀ ka-èdè, àyálò-èdè àti ipa ‘Creole’ nínú orin ìbílẹ̀ Ìlọrin.
Iṣẹ́ yìí ṣàfihàn pé iṣẹ́ ọpọlọ tó jinná ni orin kíkọ àti pé àwọn ọnà-èdè tó máa ń ṣodo sínú wọn lóríṣiríṣi ní iṣẹ́ tí kálukú wọn ń jẹ́ láti túdìí òkodoro nípa àṣà, ìṣe àti èdè àwùjọ tí onírúurú àwọn orin náà ti ń jáde.
Related Results
VIETNAMESE - EDE BILINGUAL EDUCATION IN PRIMARY SCHOOLS IN DAK LAK PROVINCE, VIETNAM
VIETNAMESE - EDE BILINGUAL EDUCATION IN PRIMARY SCHOOLS IN DAK LAK PROVINCE, VIETNAM
In Dak Lak, the Ede has the second largest population (after the Kinh). In the process of communication, the Ede language has a language contact relationship with Vietnamese. There...
Identification of neurocorrelates of loss of control eating
Identification of neurocorrelates of loss of control eating
Introduction: Loss of Control (LOC) eating leads to positive energy balance and higher instances of chronic diseases, and is, regardless of the amount consumed, defined as a subjec...
Anxiety, Depression, and Posttraumatic Stress Disorder in Patients With Induced Laryngeal Obstruction
Anxiety, Depression, and Posttraumatic Stress Disorder in Patients With Induced Laryngeal Obstruction
ImportancePatients with induced laryngeal obstruction (ILO) present with a variety of behavioral health profiles. Identifying these profiles is crucial in that behavioral health co...
Advertising and Cultural Perspective: Trophy Billboard Advertisement in Ilorin as A Paradigm
Advertising and Cultural Perspective: Trophy Billboard Advertisement in Ilorin as A Paradigm
This study examines the relationship between advertising and the culture of the Trophy Lager beer billboard advertisement at Offa garage area of Ilorin, which generated controversy...
Therapeutic Potential of Combined 5% Lifitegrast and Tocopherol Eye Drops in Managing Inflammation and Oxidative Stress in Murine Dry Eye
Therapeutic Potential of Combined 5% Lifitegrast and Tocopherol Eye Drops in Managing Inflammation and Oxidative Stress in Murine Dry Eye
Background/Objectives: This study aimed to evaluate the therapeutic effects of combined 5% lifitegrast (LF) and tocopherol (TCP) eye drops in a murine experimental dry eye (EDE) mo...
Validity and reliability of the Turkish version of the Eating Disorder Examination Questionnaire (EDE-Q-13): Short-Form of EDE-Q
Validity and reliability of the Turkish version of the Eating Disorder Examination Questionnaire (EDE-Q-13): Short-Form of EDE-Q
Abstract
Background: The Eating Disorder Examination Questionnaire (EDE-Q) is a frequently used scale to evaluate eating behaviors and attitudes. In recent years, its use h...

